Asoju orile-ede Amerika lorile-ede Naijiria Ogbeni Stuart Symington, ti ro awon omo orile-ede Naijiria lati mu igbeeru deba eto –oro aje lorile-ede Naijiria.
O tesiwaju ninu oro re wi pe sise eyi, yoo mu alekun ati idagbasoke deba eto oro-aje orile-ede Naijiria.
Ogbeni Stuart Symington, gba awon omo orile-de Naijiria nimoran yii lakooko to se abewo si alamojuto agba ile-ise International Institute of Tropical Agriculture (IITA) ti o fidi kale si ilu Ibadan ni ipinle Oyo..
Gege-bi oro re ,orile-ede Naijiria kun fun awon alumooni inu ile ti o le mu igbeeru deba eto oro-aje orile-ede Naiiria.
O tesiwaju ninu oro re wi pe orile-ede Naijiria kun fun awon ohun alumoni inu ile ,eyi ti o ye ki awon omo orile-ede yii maa dupe lowo olorun fun awon ibukun yanturu yii,ki won si lo o lati mu idagbasoke deba orile-ede Naijiria.
O tun gboriyin fun awon erongba iko oluwaadi ile-ise IITA, Pataki julo idagbasoke eto ogbin ati ise agbe lorile-ede Naijiria ati ni ile Afirika lapaapo.
Saaju, alamojuto agba ile-ise naa dokita Nteranya Sanginga se akiyesi wi pe ile-ise re ni ojuse lati se atungbekale ati igbeeru ise agbe ni ile Afirika.
O so siwaju wi pe ile-ise naa ni ojuse lati je ki awon odo ni ife kikopa ninu ise agbe nipa agbekale ise olutona re ondokowo lori ise agbe ti awon elede geesi n pe ni agri-prenuer programme.
Won ni lo lati ma ri ise agbe gege-bi ise akanse ti yoo mu owo wole ju ohun igbafe lo.
No comments:
Post a Comment