Ajo ti kii se tijoba ti oruko won n je Stand To End Rape (STER), ti seto ipolongo lodi si oyun laito asiko fawon aadota odokunrin ati odobinrin ni agbegbe Bogije nijoba ibile Ibeju Lekki nipinle Eko paapaa lori ifipabanilopo ati oyun ojiji.
Ayodeji Osowobi to je oludari ajo STER so fawon olukopa pe won ti n mura sile lati se iru eto yii fawon obi ati alagbato pelu, O ni: A seto yii ki won le nimo kikun nipa ibalopo laarin okunrin ati obinrin nitori a ti ri akosile oyun ojiji laarin omo odun mejila si meedogun pupo ni agbegbe yii ni eyi to fihan pe opolopo ninu won mo nipa ibalopo sugbon won ko mo bi o se ye ki won dena oyun nini. A n lo si awon ijoba ibile lorisiirisii lati ko won lori didena ifipabanilopo ati oyun ojiji. A nilo iranlowo awon eni kookan atijoba ki a le seto lati din oyun sise ati arun kiko nibi ibalopo ku laarin awon odo wa”
Ogbeni Edosa Oviawe to je agbenuso IPAS fun ajo adaduro kan ni Naijiria ni aisi ifitonileti ati eko kikun lori ibalopo lo n fa oyun ojiji fawon odo. O ro ijoba lati sagbateru eto ilaniloye to poju owo fawon odo pelu imoran pe ki awon obi maa farabale pelu awon omo won ki won le moo un to n sele laye awon ewe won loorekoore.
Ogbeni Sharafa Musudiku, to je olori abule Bogije dupe lowo awon ajo STER to je agbateru eto naa, o ro awon obi lati je ki awon odobinrin kawe ki won dagba ki won to maa fi won fun oko.
Odun 2014 ni won da ajo STER sile lati gbogun ti ifipabanilopo nipa idanilekoo loorekoore. Ajo STER maa n ko awon eniyan leko pelu ipese eto ilera ofe ati ilana ofin lofe fawon ti a ba ti fipabalopo lawujo.
No comments:
Post a Comment