Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Tuesday, November 14, 2017

Argentina fagba han orile-ede Russia ninu ifesewonse olorejore


Argentina vs Russia
Iko agbaboolu orile-ede Argentina ti fagba han iko agbaboolu orile-ede Russia ti yoo sagbateru idije boolu afesegba lagbaye todun 2018 pelu ami ayo kan sodo(1-0),  ninu ifesewonse olorejore ti o waye laarin iko mejeeji ohun fun igbaradi idije agbaye to n bo lona.
Atamatase iko agbaboolu Argentina Sergio Aguero lo gba ami ayo kan soso ohun wole niseju merindinlaadorun saa keji ifesewonse ohun ni papa isere Luzhniki  ti o wa nilu Moscow lorile-ede Russia.
Gege bi akonimoogba agba iko agbaboolu orile-ede Argentina Jorge Sampaoli “ A mo wipe ifesewonse ohun yoo le pupo, nitori gbogbo ero wa pata lo wa si imuse ninu ifigagbaga yii,
A gba boolu pelu igboya, besini a tun kopa daradara lowo eyin wa lati dena boolu Kankan lati wole. Eyi je ohun iwuri ati esi ti o dara pupo fun gbogbo wa lapapo.”
Bi o tile jepe, iko agbaboolu orile-ede  Russia kopa ribiribi ninu ifesewonse ohun, sugbon omi po ju oka lo, iko agbaboolu Argentina jawe olubori.
Iroyin tun so pe,  ifesewonse ifigagbaga ohun ni o je ifesewonse akoko ti yoo waye ni papa isere ohun lati gba ti o ti wani tuntun se. bakan naa, ni yoo je papa isere ti won yoo fi side idjje boolu agbaye ohun to n bo lodun 2018.
Ni afikun, iko agbaboolu Argentina yoo tun lo koju iko agbaboolu Super Eagles ti orile-ede Naijiria ni papa isere Krasnoda  ti o kogun si ekun gusu iwo orun orile-ede Russia, lojo kerinla osu kokanla odun ti a wayii.
Bakan naa, ni orile-ede Russia yoo tun lo koju orile-ede Spain ni papa isere St Petersburg  lojo kan naa, ninu ifesewonse olorejore fun igbaradi idije boolu agbaye ohun to n bo lona.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages