Igbakeji aare Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo ti nijoba apapo Naijiria ti setan lati tete mojuto oro awon eniyan Naijiria ti won fi oke okun se ibujoko paapaa ni orile-ede Lybia atawon ile Geesi.
Yemi Osinbajo soro yii lojo Ru nilu Abuja lasiko to n se ipade pelu awon olori ile ise ijoba to n risi oro igbokegbodo awon eniyan Naijiria lataari ase ti Aare Muhammadu Buhari pa lati mojuto oro awon eniyan Naijiria ti won wa ni Lybia bayii.
Aare Buhari pase pe ki igbakeji aare atawon ile ise torokan dide si fifopin si isoro awon asatipo omo Naijiria to wa ni Lybia bayii.
Awon miran ti won wa nibi ipade yii ni minista abele fun oro ile okeere, Khadija Abba-Ibrahim; alase ajo awon asatipo ni Naijiria, Hajiya Sadiya Umar –Farouk; alase ajo to n gbogunti kiko awon eniyan lo singba NAPTIP, Abileko Julie Okah-Donli atawon miran.
Ninu atejade Aare ti Garba Shehu to je oluranlowo aare lori ifitonileti fi sita lojo Ru lo ti seleri lati din iwon awon eniyan Naijiria to n lo sile Euroopu lati agbami okun Mediterranean ati asale. Aare ni eyi yoo di sise nipase ipese awon ohun amayederun nile yii fawon eniyan bii eto eko to ye kooro, eto ilera to yaranti, ohun jije ati eto aabo fun emi ati dukia gbogbo olugbe Naijiria.
No comments:
Post a Comment