Aare Muhammadu Buhari ti pinnu lati sabewo sawon ipinle ti wahala sele si laipe bii Benue, Yobe, Zamfara, Rivers ati Taraba.
Ogbeni Femi Adesina to je oluranlowo Aare lori eto iroyin lo so eyi di mimo sugbon ko so gbendeke asiko ti Aare yoo se abewo yii.
O ni: Aare Buhari yoo sebewo sawon ipinle yii bi eyi ti won ti ji awon akekoobinrin aadofa ko lo lati oni, ojo karun un, osu keta, Aare yoo lo si Taraba ko to gba Benue lo si Yobe ko to lo si Zamfara ko to pari irinajo naa si Rivers.”
Adesina ni Aare Buhari n figbagbogbo jiroro pelu awon gomina ipinle ti oro kan ki won le jo mo ojutu si awon isoro eto aabo ipinle kookan.
Ni ipari o ro awon eniyan orile ede Naijiria lati tubo maa gbe ni alaafia pelu ileri lati se idajo to ye sawon onise ibi ti oro kan.
No comments:
Post a Comment