Zlatan Ibrahimovic ti pinnu lati fi iko Manchester United sile lati darapo mo iko agbaboolu LA Galaxy.
Omo odun mẹ́rìndínlógójì ohun nireti ti wa tele pe yoo darapo mo iko naa laipe.
Gege bi Ibrahimovic se so lori ero ayelu“ko si ohun ti o ni ibere ti o lopin, asiko ti to ni bayii lati tun tesiwaju ninu irin-ajo boolu afesegba mi, leyin saa meji ti mo lo pelu iko agbaboolu Manchester United. Mo dupe pupo fun iko naa, awon ololufe, awon akegbe mi, awon akonimoogba gbogbo ati awon osise patapata fun aseyori mi ninu iko yii.”
Akonimoogba agba iko Manchester United, Jose Mourinho naa ti so tele ri pe, Ibrahimovic yoo kuro ninu iko naa ti iwe isise re naa ba wasi ipari ni saa yii.
No comments:
Post a Comment