Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Saturday, April 21, 2018

Antonio Conte gboriyin fun Victor Moses

Akonimoogba agba iko agbaboolu Chelsea, Antonio Conte ti gbosuba kare lai fun agbaboolu re omo bibi ati agbaboolu kan gbogi ninu iko Super Eagles Naijiria, Victor Moses.
Moses gba ami ayo kan wole, ti o si se iranwo ami-ayo kan lati ran iko agbaboolu Chelsea lowo lati jawe olubori ninu ifesewonse pelu iko agbaboolu Burnley ni papa isere Turf Moor.
Bi o ti le je pe, Ashley Barnes da ami-ayo kan pada, lati so esi ifesewonse ohun di ami ayo kan si meji(1-2), sugbon omi po ju oka lo.
Gege bi Antonio Conte se so,”A kopa ribiribi lo ni, bee si ni, a ni eto si ami meteeta ohun, ni papa julo, Moses se gudugudu meje ohun yaya mefa, leyin ti o gba ami-ayo kan wole t o si tun se iranwo ami-ayo kan.”
Ewe,” ji jawe olubori ninu ifesewonse otooto meji lera yoo se iranwo n la fun wa lati kopa daradara ninu awon ifesewonse wa miran to n bo lona.”
Ni bayii, Chelsea yoo lo koju Southampton ninu ifigagbaga ipele keji si asekagba idije FA lojo Aiku(Sunday).

fun awon ere idaraya miran ni ede geesi  kan si

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages