Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Monday, April 9, 2018

Commonwealth: Naijiria fagbahan Malaysia ninu ifigagbaga boolu ori tabili



Iko agbaboolu ori tabili Naijiria ti bere ifigagbaga won ninu idije Commonwealth Games to n lo lowo lorile-ede Australia.
Iko Naijiria fagbahan Malaysia ati Belize ninu ifigagbaga akoko ti o waye lojoBo(Thursday).
Olajide Omotayo fagbahan Chee Feng  olukopa fun Malaysia pelu ami-ayo metala si mokanla(13-11), marundinlogun si metala(15-13), mokanla si meje(11-7) ni itele n tele.
Bakan naa, ni Omotayo tun gbo ewuro soju akegbe re lati orile-ede  Belize Rohit Pagarani pelu ami-ayo (11-4), (11-2), (11-2).
Bee sini, Bode Abiodun naa tun fagbahan Mohammed Rizal  lati Malaysia pelu ami-ayo (11-5), (11-7),(13-11) ninu ifigagbaga keji re, leyin ti o ti fagbahan Devesh Hukmani torile-ede Belize ninu ifigagbaga akoko pelu ami-ayo (11-5), (11-3), (11-2).
Ninu ifigagbaga apapo olukopa meji (men’s team doubles), bi o ti le jepe, Azeez Jamiu ati Olajide Omotayo fagbahan Terry Su ati Devesh Hukmani ti won wa lati orile-ede Belize pelu (11-6), (11-4), (11-5), sugbon omi poju oka lo leyin ti won padanu ifigabaga elekeji sowo Javen Choong ati Chee Feng Leong lati Malaysia pelu ami-ayo (4-11), (9-11),(7-11).
Ni bayii, Abiodun yoo lo koju Javen Choong lati Malaysia ati Terry Su lati Belize, beesini Jamiu naa yoo lo koju Rohit Pagarani lati Belize.
Idije Commonwealth Games yii, ni yoo di igba ketala ti Naijiria yoo kopa ninu re lati odun 1950.
Ewe, iko Naijiria yoo maa fojusona lati tun fitan miran bale ti yoo koja eyi ti orile-ede ohun ni tele ninu irufe idije naa ti o waye lodun 1994 ni  Canada, leyin ti won gba ami-eye mẹ́tàdínlógójì  ninu idije naa.
Bakan naa, ninu idije Commonwealth Games ti o waye ni Glasgow, lorile-ede Scotland lodun 2014,  Naijiria gba ami-eye mẹ́rìndínlógójì, ti n se (11 Gold, 11 silver ati 14 bronze).
Ni ipari, idije Commonwealth ohun ti o bere lojoRu(Wednesday), ni ireti wa pe yoo pari lojo karundinlogun osu kerin odun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages