Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣe ipade ita gbangba awọn alẹnulọrọ ni gbagede wọn ni Ikẹja. Ipade naa lo da lori agbekalẹ Abadofin kan ti wọn fi n ṣeto lati maa fun awọn ara ilu ni aami ẹyẹ lori iṣẹ takuntakun wọn fun idagbasoke ipinlẹ Eko lapapo, eleyii ti yoo nii ṣe pẹlu iṣẹ ati ojuṣe olukuluku.
Abadofin ti wọn ṣagbeyẹwo ninu ipade ita gbangba naa ti wọn pe akori rẹ ni “Abadofin Ṣiṣe Agbekalẹ Ofin Ti Yoo Ṣe Idasilẹ Ilana Fifun Awọn Ara Ilu Laami Idanilọla Ti Wọn Yoo Ti Wo Ti Won Yoo Tun Fi Tọka Si Anfani Ti Ẹni To Gba Aami Idanilọla Yoo Ni”, ni Agbenusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọ ju ninu Ile, Aṣofin Sanai Agunbiade sọ pe igbesẹ to dara ni Abadofin naa lati maa mo riri iṣẹ aṣeyọri ni ipinlẹ yii. O ni, “gẹgẹ bi ipinrọ keji orin orilẹ-ede wa Nigeria, pe ‘kiṣe awọn akọni wa ko ma ṣe ja si ofo’ , eleyii lo ṣe jẹ ki a pe ipade yii, ki a le fi ero ti yin kun abadofin naa”. O ni bi wọn ba sọ Abadofin naa di Ofin, yoo jẹ ki wọn mọ riri awọn iṣẹ aṣeyọri, iṣẹ akin ati iṣẹ takuntakun laarin ilu.
Igbakeji Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọ ju ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Muyiwa Jimoh, ti o ṣe atupalẹ Abadofin ṣalaye pe Abadofin naa ti o pin si abala mẹrindinlọgbọn ni yoo jẹ akọkọ iru rẹ paapaa ni awọn ipinlẹ lorilẹ-ede yii, elyii to ni opin si ipele meji, iyẹn Idanilola atu ati Aami Ẹyẹ.
Lara akiyesi awọn alẹnulọrọ ninu ipade naa ni ki awọn alaami ẹyẹ naa ma ma yan ara wọn fun igbimọ to n moju to ami idanilọla bayii, eleyii ti akọwe agba Ile-iṣẹ ijọba fun ọrọ iṣẹ ilu Pataki kan, Ọmọwe Jẹmilade Longẹ woye rẹ
Bakan naa Akọwe Agba fun Ile-iṣẹ Ijoba to n ri Isuna-owo ni Ipinlẹ Eko, Arabinrin Olufunmilayọ Balogun sọ pe ko si abala ti yoo maa gba aami idanilọla naa pada lọwọ ẹni ti wọn ba fun, bi iru ẹni bẹẹ ba ṣe aṣemaṣe lọjọ iwaju. Bẹẹ ni wọn tun woye pe o yẹ ki ami ẹyẹ fun ẹka eto ẹkọ ṣe pataki ninu Ofin naa.
Ninu idahunn rẹ, Aṣofin Agunbiade ṣọ pe gbogbo akiyesi yii ni wọn yoo tun ṣagbeyẹwo rẹ ki Abadofin naa to di Ofin.
Alaga Igbimọ tẹẹkoto fun ọrọ iṣẹ pataki kan laarin ilu ati Ibaṣepọ Ẹka Ijọba ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, ti wọn ṣagbateru ipade itagbangba naa, Aṣofin Hakeem Shokunle ninu ọrọ rẹ fi mulẹ pe igbesẹ yii yoo le jẹ ki ijoba Ipinlẹ Eko ṣe kori-o-ya fun ṣiṣe iṣẹ aṣeyọri ni ipinlẹ yii. O ni pe ilana naa ko ni faaye gba ọna aitọ, yoo da lori otitọ ati iwa rere.
O ni, “bi a ba fun eniyan ni ami ẹyẹ yii lori iṣẹ takuntakun ti ẹnikan ti ṣe, yoo je nnkan iwuri fun awọn to wa laye ati awọn to n bọ lẹyin nitori ti a ba bẹrẹ ati maa fun awọn eniyan ni ami idanilọla yii, lapa kan, wọn ko ni jawọ ninu iṣẹ takuntakun wọn fun ilu, bẹẹ ni yoo jẹ ohun iwuri fun awọn to n bọ lẹyin naa”.
Lara awọn ile-iṣẹ ijọba Ipinlẹ Eko ti wọn ṣoju fun ninu ipade itagbangba awon alẹnulọrọ naa ni Ile-iṣẹ ijọba fun eto Ẹkọ; Ile iṣẹ ijọba fun Iṣuna-owo ilu, ẹka Idajọ, ile-iṣẹ ijọba fun iṣẹ Pataki ilu, ati awọn miiran
No comments:
Post a Comment