Ninu ipo ate ajo to n ri si boolu afesegba lagbaye FIFA, ti o sese jade, Naijiria bo si ipo mẹ́tàdínláàdọ́ta lagbaye, ti won si di ipo kefa mu nile Afrika pelu apapo ami ẹgbẹ̀ta le márùndínlógójì ti iko ohun ni.
Ninu ipo ate keyin ti o jade, Naijiria wa ni ipo méjílélógójì lagbaye pelu ami ẹgbẹ̀ta o le mesan lori tabili.
Ewe, orile-ede Tunisia ni o wa loke julo saaju orile-ede miran nile Afrika, leyin ti won di ipo kerinla mu lagbaye, ti Senegal ati DR Congo si di ipo méjídínlọ́gbọ̀n ati ipo méjídínlógójì ni itele n tele.
Germany si duro loke tente tabili ipo ate lagbaye, ti Brazil si tele won, Belgium bo si ipo keta lati ipo karun-un ti won wa tele.
Bakan naa, awon orile-ede ti Naijiria yoo maa waako pelu ninu idije boolu agbaye to n bo lona, Argentina, Croatia ati Iceland wa ni ipo karun-un, ipo kejidinlogun ati ipo kejilelogun ni itele n tele.
Ipo ate iko agbaboolu orile-ede mewa nile Afrika ni itele n tele lori tabili.
Tunisia – pelu ami ẹ̀gbẹ̀rún le mejila lori tabili
Senegal – ẹgbẹ̀rin le marundinlogbon
Congo DR – ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin le mokanla
Morocco – ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin din mokandinlogun
Egypt – ẹgbẹ̀ta le mẹ́rìndínlógójì
Nigeria – ẹgbẹ̀ta le márùndínlógójì
Cameroon – ẹgbẹ̀ta le meta
Ghana – ẹgbẹ̀ta le meta
Burkina Faso – ẹgbẹ̀ta din mesan
Cape Verde Islands – ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta le márùndínláàdọ́ta
Ni bayii, Ipo ate ajo FIFA miran yoo tun jade lojo ketadinlogun osu karun un odun ti a wa yii.
No comments:
Post a Comment