Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Saturday, April 21, 2018

Oba –birin Elizabeti fe ki omo oba – kunrin re gba ipo .



Oba-birin Elizabeti keeji ti rawo ebe si awon omo egbe Ajo Commonwealth lati gbe ipo adari egbe naa fun omo re Omo-oba kunrin Charles
O so eyi di mimo bi o se n si ipade awon olori orile-ede ti won je omo egbe Ajo naa,ti o waye nilu London lorile-ede Britiko.
Ipo yi ko ki n se oye idile ,ko si  pon dandan ki won gbe oye naa fun Omo oba-kunrin naa ti Oba-birin naa ba papoda.
Awon olori orile-ede metalelaadota naa peju si aafin Buckingham lati pinnu lori eni ti yo gba ipo naa.
Lakoko to n ba awon ti won n kopa nibi ipade naa soro ,awon omo-oba ati olori ijoba orile-ede naa, Oba –birin Elisabeti   so wi pe,ireti oun  ni wi pe Ajo naa yoo tesiwaju fun iran ojo iwaju,nigba ti Omo –oba  kunrin naa yoo si tesiwaju ninu ojuse baba re eyi ti o beere l;odun 1949.
Lara ohun ti won jiroro le lori ni, oro to niise nipa eti okun, eto abo lori ero alatagba,ati eto idokowo laarin awon orile-ede ti won je omo-egbe.
Olorin Emeli Sande ni o si ipade pelu orin orile-ede naa ni gbogan ti asia gbogbo awon omo egbe metalelaadota wa.
Olori ijoba orile-ede Britiko Theresa May so fun awon olori orile-ede naa wi pe oun gbagbo wi pe Ajo naa yoo tesiwaju ninu ojuse re ti yoo si so eso rere.
Bakannaa, o dupe gidi lowo Oba-birin naa fun gbigba alejo ipade naa,ti o si se apejuwe re ni “asegun ti o duro sinsin
Saaju ninu oro re,Omo-oba kunrin Charles so fun awon olukopa wi pe Ajo Commonwealth titun yi ni ojuse lati se,oun si gba ladura wi pe ipade naa yoo tun mu ibasepo to danmoran wa laarin awon orile-ede metalelaadota naa,
O le ni awon ogorun oloogun  ti won duro leselese niwaju afin naa , ti won duro sepesepe ,ti won si yinbon ota metalelaadota lati si ipade naa.
Awon olori orile-ede merindinlaadota lo kopa ninu ipade naa ti awon yoku si je minisita fun oro ile okeere lorile-ede won.
Awon omo oba Camilla, Harry ati Williams ni won kopa ninu ipade naa.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages