Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Saturday, April 21, 2018

Omo Aare ana lorile-ede South Africa yoo fojuba ile-ejo



Omo Aare ana lorile-ede South Africa Duduzane  Jacob  Zuma  yoo fojuba ile-ejo lori esun ipaniyan nipa oko – ayokele.
Eyi waye lakoko ti o fi oko re pa arabirin Phumzile Dube ninu odun 2014, eyi ti won ti fagile eto igbejo naa teleri.
Igbimo olupejo lorile-ede naa National Prosecuting Authority (NPA)fun omo Aare naa ni gbegede osu meji eyi ti o wa sopin ni opin osu keta odun lati so idi ti ko fi ye ki o fojuba ile-ejo ,sugbon o kuna lati se eyi,gege-bi agbenuso ile-ise naa Luvuyo Mfaku  se so.
Erongba lati gbo oro lenu omo Aare ana naa forisanpon , bee si ni awon agbejoro re ko si nitosi lati foroworo lenu won.
Awon agbejoro lorile-ede naa ti pinnu lati gbe Ogbeni Duduzane Jacob Zuma lo si ile –ejo .
Ninu osu kewa odun ti o koja ni egbe ajafetomoniyan Afriforum so wi pe awon yoo funrara awon pe omo Aare ana naa lejo ti Ajo NPA ba ko lati se eleyi,eyi lo si sokunfa igbese ti Ajo NPA naa gbe bayi,
Nibayi, Ogbeni Mfaku so wi pe awon ko mo ojo tabi akoko ti Ogbeni Duduzane  Jacob Zuma yoo fojuba ile-ejo.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages