Aare Muhammadu Buhari ti o n tuko ijoba orile-ede Naijiria, ti yannana patakii ati mimu idagbasoke ba ere-idaraya lorille-ede Najiria, bakan naa nile Afrika.
Aare Buhari so oro ohun di mimo lasiko to n se ipade po pelu awon minisita to n ri si ere-idaraya nile Afrika, ipade eyi ti o waye ni gbagede ECOWAS Parliament nilu Abuja lojoru(Wednesday).
O tesiwaju pe, patakii ipade ohun ni lati jo-jiroro bii idagbasoke yoo se de ba ere-idaraya nile Afrika.
“Inu mi dun pupo, besini o je ohun iwuri lati ri iru igbese nla yii lati mu idagbasoke ba ere-idaraya nile Afrika, eleyi ti o je eri nipa dida igbimo tuntun (African Union Council), leyi ti o ma ri si mimu idagbasoke ba ere-idaraya.
Gege bi a ti mo pe, ere-idaraya se pataki si orile-ede Naijiria, eyi je idi pataki ti a fi se agbateru ipade yii”.
No comments:
Post a Comment