Ijoba orile-ede Tanzania so fun ajo isokan orile-ede agbaye lati se iwadii lori iku to pa awon omo-ogun re merinla lose to koja, nigba ti won n sise ipetusaawo lorile-ede Demoracratic Republic of Congo
Nibi ayeye idagbere ikeyin fun awon oloogbe naa, olori ijoba orile-ede Tanzania, Kassim Majaliwa so pe,awon molebi ati ijoba fe mo ni pato ohun ti o sele gan-an.
Ijoba orile-ede Tazania n pe ajo agbaye lati bere iwadii to ye kooro lori itaje awon omo-ogun orile-ede Tanzania sile, lati le fimu iru awon odaran bee danrin.
Ijoba ohun so pe, “ireti wa ni pe, ki won tete se iwadii yii aipe ojo”.
Ikolu yii je eyi ti o buru ju ninu ikolu ti won n se tako awon omo-ogun apetusaawo ajo isokan agbaye latojo pipe.
Ajo agbaye gbagbo pe, awon omo-ogun olote orile-ede Uganda ti won satileyin fun awon omo-ogun olote orile-ede Congo ni won yoo debi ikolu ohun lu, amo a koi ti fi idi ododo oro naa mule.
No comments:
Post a Comment