Aare Muhammadu Buhari ti fi idunnu re han lori igberu ti o n ba eto ogbin, igbese kan gboogi lati pese ise fun awon odo langba lorile-ede Naijiria.
Nigba ti o n gbalejo minisita fun oro ile okere lorile-ede Tunisia, Boukekri Rmilli nile-ise Aare lojo-Isegun nilu Abuja, Aare Buhari so pe, isakoso oun yoo se alekun atileyin fun eto ogbin, ti o je ona kan gboogi lati pese ise.
Aare Buhari so pe, “A n sa gbogbo akitiyan wa lati pese ise fun awon odo wa, a n igbese to nipon ni eka eto ogbin, latari sege-sege oja epo-robi ati airise se awon eniyan lorile-ede Naijiria, a setan lati fi igbagbo wa sori eto ogbin, inu mi dun pe awon odo langba wa n sise agbe bayii dipo ki won maa duro de ise alakowe, won n laagun ninu oorun lowolowo, eyi ti won yoo kere re laipe, tori pe eto ogbin ni ona abayo lowo ti a wa yii”.
O fi kun oro re pe, oun mo akitiyan ti isakoso ijoba orile-ede Tunisia ti gbe lori eto ogbin, irinajo afe, ati eto-ilera, laipe ojo, a o se agbekale iko kan ti yoo se abewo si orile-ede ohun lati mo awon eka ti awon orile-ede mejeeji ohun yoo ti sise papo.
Ninu oro re, o fi idunnu re han nipa agbende ipade apero iko laarin orile-ede mejeeji, eyi ti ogoro awon asoju ni olokan-o-jokan eka ati awon onisowo jankan-jankan ti kopa.
Rmilli, eni ti o dari iko awon onisowo lati orile-ede Tunisia so fun Aare naa pe, orile-ede oun n saniyan lori amugberu eto oro-aje pelu orile-ede Naijira.
O fi idunnu re han lori bi awon oludokowo se jade lopo yanturu lati kopa nibi apapo ipade apero awon olokowo orile-ede Naijiria ati orile-ede Tunisia to waye nilu Abuja lojo-Aje.
Minisita oun jise pataki fun Aare Buhari, ninu eyi ti Aare orile-ede Tunisia Beji Caid Essebsi, ti ki olori orile-ede Nigeria ku oriire fun aseyori ninu eto-abo, oro-aje ati ipa ti o n ko ni ile Afrika.
No comments:
Post a Comment