Ile-igbimo asofin lorile-ede Nigeria ti ro Aare Muhammadu Buhari lati kede pajawiri ni eka eto ilera, lori ohun ti won sapejuwe bi awon ohun elo irin-ise ati awon ohun amayederun ni awon ile-iwosan se baje.
Ile-igbimo ohun tun so fun awon alase lati maa pese owo ti o towo fun eka naa, ninu eto isuna owo odun 2018, o kere tan ile-iwosan ijoba kan ni awon ekun mefeefa kaakiri orile-ede Naijira lodoodun
Eyi waye lori aba kan ti o dale, “Idi Pataki fun kikede pajawiri ni eka ile-iwosan lori awon ohun elo ti o ti baje tan”.eyi ti asofin Suleiman Hunkuyi se agbateru re ninu ipade ti o waye lojo-Isegun.
Asofin Hunkuyi lasiko ijiroro lori aba kan pe, bi awon ohun elo amayederun ni awon ile-iwosan ijoba ko seyin, “ daku-daji ina mona-mona, ati aisi oni deedee, eyi ti o sokunfa ailera-ara ati alekun ewu kiko aarun ni awon ile-iwosan”.
O woye pe, gbogbo awon ero ti won n se ayewo ara bi: MRI, CT scan ati ultrasound ati awon ohun elo miiran ni won ko sise mo tabi ti ko si won nile-iwosan naa.
Gege bi oro asofin Hunkuyi pe, “Awon ohun ti o n sele ni awon ile-iwosan wa ti se alekun bi awon omo orile-ede Naijiria se n lo setoju ara won loke okun, pelu fifi oju wina owon-gogo owo ile okere, lati toju ara won lorile-ede America, ile-Europe, ile Asia ati awon orile-ede miiran nile Afrika.
Omo bibi ipinle Kaduna oun so pe, osuwon akosile ajo UNICEF laipe yii safihan iku alaboyun ati awon omo-wewe lorile-ede Naijiria si ipo keji lagbaye, eyi ti o tunmo si pe, a n padanu egberun lona mokanla o-le 2, 300 awon omowewe ti ojo ori won koi ti pe odun marun-un ati aadojo 145awon alaboyun lasiko ibimo lojoojumo.
Ninu oro tire, asofin Aliyu Sabi Abdullahi pe fun idasile ohun elo iwosan ijoba kookan ni awon ekun mefeefa, ni iyanju ati wa ojutu si isoro awon ile-iwosan ijoba lorile-ede Naijiria, eyi le seese nipa akitian ile-igbimo asofin, latari ati se adinku orisirisi aisan ti o n seyo lorile-ede Naijiria.
No comments:
Post a Comment