Adari ile-ise to n mojuto awon osise lorile ede Naijiria ,arabinrin Winifred Oyo-Ita ti ni ,bi igbimo ti igbakeji aare orile-ede Naijiria Yemi Osinbanjo n sakoso le lori se da awon oga agba mefa to n sakoso ajo to n mojuto isele pajawiri iyen NEMA duro wa ni ibamu pelu ilana.
Bakan naa, adele oludari ajo to n mojuto sise owo ilu kumo-kumo EFCC, ogbeni Ibrahim Magu salaye pe ajo EFCC lo kowe si ile-ise igbakeji aare lati fun awon oga agba mefa naa ni iwe gbele re, fun igba die lati le je ki won ri awon iwe to se koko ti won fe lo fun iwadii won.
Awon ajo mejeeji yii salaye , nigba ti won n fara han niwaju ile igbimo asoju-asofin to n sako lori ajo NEMA, nipa iwadii lori awon ise ti ajo naa n se.
Awon oludari eka ajo naa ti won da duro lenu ise ni ,adari eto inawo ati iwe isiro, , Akinbola Hakeem Gbolahan, adele fun adari eka fun ise akanse, ogbeni Umesi Emenike;adari fun eka to n ri si isele pajawiri ,Mallam Alhassan Nuhu; adari awako isele pajawiri ofurufu ,ogbeni Mamman Ali Ibrahim, oludari eka to n mojuto irinse, ogbeni Ganiyu Yunusa Deji; ati oludari eka to mojuto eto iranwo , ogbeni Kanar Mohammed.
Iyaafin Winifred Oyo-Ita so pe igbese ti igbakeji aare ati awon igbimo to n sakoso ajo naa, gbe wa ni ibamu pelu ilana ofin to ro mo awon osise ijoba lati da awon adari eka ajo naa ati awon osise won duro .
O salaye siwaju pe, igbimo to n sakoso ajo naa ni agbara lati da awon oludari eka ajo ati awon osise duro ti won ba tapa si ofin.
Ile igbimo asofin ranse si oludari ile –ise ati ajo ti ijoba apapo lati wa salaye nipa ilana to ro mo dida awon osise ajo naa duro boya igbimo to n sako ajo naa ni agbara labe ofin lati awon oludari eka ajo mefa naa duro lenu ise.
Mustapha Suleiman akowe agba , to tun soju fun oludari ile ise to n sakoso gbogbo ile-ise ati ajo ti ijoba apapo tanna imole si ilana to ro mo ijiya to wa labe ofin awon osise ijoba, fun eni to ba tapa si ofin naa.
No comments:
Post a Comment