Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Tuesday, April 24, 2018

Mohamed Salah gba ami-eye PFA ninu idije EPL



Atamatase omo orile-ede Egypt, ti o tun n kopa fun iko agbaboolu Liverpool ninu idije ile geesi, EPLMohamed Salah ti ta yo laarin awon akegbe re yooku lati gba ami eye agbaboolu nnu idije ile geesi ti o darajulo ti a mo si, PFA player of the year lojo Aiku(Sunday).
Ewe Salah ti gba ami-ayo mọ́kànlélógójì sinu agbon fun iko re Liverpool ni saa yii, saaju akegbe re ti o n kopa fun iko agbaboolu Manchester City Kevin de Bruyne.
Salah fi idunnu re han lasiko ayeye igbami eye ohun pe, “O je ohun ti o bu ola pupo fun mi. Mo ti sise takuntakun bee si ni inu mi dun lopolopo lati gba ami-eye yii.”
Awon akegbe re yooku ti won jo figagbaga du ami-eye ohun ni:
David Silva, De Bruyne, Harry Kane
Ninu ami-eye miran:
Ami-eye agbaboolu odo ti o darajulo – Leroy Sane
Asole ti o darajulo – David De Gea
Gege bi akonimoogba agba iko Manchester City, Pep Guardiola, O ni, bi won n ba n se agbeyewo ipa agbaboolu kookan ninu idije EPL saa yii, osuwon agbaboolu re Kevin de Bruyne ni o kun julo, ti o si leto si ami-eye ohun, yala nipa iranwo ami-ayo, tabi ka gba boolu sinu agbon.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages