Your campus No 1 Website

Business

test

Breaking

Post Top Ad

Your Ad Spot

Saturday, April 21, 2018

Ogbontarigi akorin omo orile-ede Tanzania toro aforiji.

Image result for Diamond Platnumz
Diamond Platnumz
Ogbontarigi akorin omo orile-ede Tanzania Diamond Platnumz ti toro aforoji fun fonran ti o gbe sori ero kalekako Instagram, eyi ti o se afihan re nibi ti o fenuko obirin lenu.
O pa oju fonran naa re ni ibere ose yi leyin ti awon olopa fi oro wa lenu wo.
Awon alamojuto abo ri fonran naa gege-bi eyi ti o tabuku omoluabi, tabuku asa ati ise orile-ede Tanzania ati ofin lori ero alatagba.
Ogbontarigi olorin naa ti o gba ami eye “bongo flava” so fun awon akoroyin wi pe ,oun ri wi pe iwa yi ko bojumu rara gege-bi eni ti awon odo n wo lawokose.
Titoro aforiji waye leyin ipade ti o se pelu awon alase orile-ede naa ni ile-ise to n se amojuto gbogbo eka ibanisoro lorile-ede naa,ti won si se agbekale ofin kan ti o fa ariyanjiyan ni bi ose melo seyin.
Ajo naa ninu ofin re  so fun awon oniroyin lori ero alatagba lati san  owo itanran ati lati foruko sile pelu iye owo ti o to  oodunrun owo dola.
Ogunlogo awon ajafetomoniyan ,awon onile- ise lori ero alatagba ati awon ti won n se amulo ero alatagba fesun kan ijoba orile-ede naa wi pe ofin yi tako eto omo eniyan.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com

Post Top Ad

Your Ad Spot

Pages